25 Njẹ nisisiyi, wo o, emi mọ̀ pe gbogbo nyin, lãrin ẹniti emi ti nkiri wãsu ijọba Ọlọrun, kì yio ri oju mi mọ́.
26 Nitorina mo pè nyin ṣe ẹlẹri loni yi pe, ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia gbogbo.
27 Nitoriti emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin.
28 Ẹ kiyesara nyin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmí Mimọ́ fi nyin ṣe alabojuto rẹ̀, lati mã tọju ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ rà.
29 Nitoriti emi mọ̀ pe, lẹhin lilọ mi, ikõkò buburu yio wọ̀ ãrin nyin, li aidá agbo si.
30 Ati larin ẹnyin tikaranyin li awọn enia yio dide, ti nwọn o ma sọ̀rọ òdi, lati fà awọn ọmọ-ẹhin sẹhin wọn.
31 Nitorina ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã ranti pe, fun ọdún mẹta, emi kò dẹkun ati mã fi omije kìlọ fun olukuluku li ọsán ati li oru.