14 Nwọn si tọ̀ olori awọn alufa ati awọn àgbagba lọ, nwọn si wipe, Awa ti fi èpe nla bu ara wa pe, a kì yio tọ́ ohun nkan wò titi awa ó fi pa Paulu.
15 Njẹ nisisiyi ki ẹnyin pẹlu ajọ igbimọ wi fun olori-ogun, ki o mu u sọkalẹ tọ̀ nyin wá, bi ẹnipe ẹnyin nfẹ wadi ọ̀ran rẹ̀ dajudaju: ki o to sunmọ itosi, awa ó si ti mura lati pa a.
16 Nigbati ọmọ arabinrin Paulu si gburó idena wọn, o lọ, o si wọ̀ inu ile-olodi lọ, o si sọ fun Paulu.
17 Paulu si pè ọkan ninu awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o ni, Mu ọmọkunrin yi tọ̀ olori-ogun lọ: nitori o ni nkan lati sọ fun u.
18 O mu u, o si sìn i lọ sọdọ olori-ogun, o si wipe, Paulu ondè pè mi sọdọ rẹ̀, o si bẹ̀ mi pe ki emi mu ọmọkunrin yi tọ̀ ọ wá, ẹniti o ni nkan lati sọ fun ọ.
19 Olori-ogun fà a lọwọ, o si lọ si apakan, o si bi i lere nikọkọ pe, Kili ohun ti iwọ ni isọ fun mi?
20 O si wipe, Awọn Ju fi ìmọ ṣọkan lati wá ibẹ̀ ọ ki o mu Paulu sọkalẹ wá si ajọ igbimọ li ọla, bi ẹnipe iwọ nfẹ bère nkan dajudaju nipa rẹ̀.