16 Awọn ẹniti mo si da lohùn pe, Kì iṣe iṣe awọn ara Romu lati da ẹnikẹni lẹbi, ki ẹniti a fisùn ki o to kò awọn olufisùn rẹ̀ loju, ki o si ri àye wi ti ẹnu rẹ̀, nitori ọ̀ran ti a kà si i lọrùn,
17 Nitorina nigbati nwọn jùmọ wá si ihinyi, emi kò jafara, nijọ keji mo joko lori itẹ́ idajọ, mo si paṣẹ pe ki a mu ọkunrin na wá.
18 Nigbati awọn olufisùn na dide, nwọn kò kà ọ̀ran buburu iru eyi ti mo rò si i lọrùn.
19 Ṣugbọn nwọn ni ọ̀ran kan si i, niti isin wọn, ati niti Jesu kan ti o ti kú, ti Paulu tẹnumọ́ pe o wà lãye.
20 Bi emi kò si ti mọ̀ bi a iti wadi nkan wọnyi, mo bi i lere bi o nfẹ lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀.
21 Ṣugbọn nigbati Paulu fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, pe ki a pa on mọ fun idajọ rẹ̀, mo paṣẹ pe ki a pa a mọ titi emi o fi le rán a lọ sọdọ Kesari.
22 Agrippa si wi fun Festu pe, Emi pẹlu fẹ lati gbọ́ ọrọ ọkunrin na tikarami. O si wipe, Lọla iwọ o gbọ ọ.