17 Nitorina nigbati nwọn jùmọ wá si ihinyi, emi kò jafara, nijọ keji mo joko lori itẹ́ idajọ, mo si paṣẹ pe ki a mu ọkunrin na wá.
18 Nigbati awọn olufisùn na dide, nwọn kò kà ọ̀ran buburu iru eyi ti mo rò si i lọrùn.
19 Ṣugbọn nwọn ni ọ̀ran kan si i, niti isin wọn, ati niti Jesu kan ti o ti kú, ti Paulu tẹnumọ́ pe o wà lãye.
20 Bi emi kò si ti mọ̀ bi a iti wadi nkan wọnyi, mo bi i lere bi o nfẹ lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀.
21 Ṣugbọn nigbati Paulu fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, pe ki a pa on mọ fun idajọ rẹ̀, mo paṣẹ pe ki a pa a mọ titi emi o fi le rán a lọ sọdọ Kesari.
22 Agrippa si wi fun Festu pe, Emi pẹlu fẹ lati gbọ́ ọrọ ọkunrin na tikarami. O si wipe, Lọla iwọ o gbọ ọ.
23 Njẹ ni ijọ keji, ti Agrippa on Bernike wá, ti awọn ti ọsọ́ pipọ, ti nwọn si wọ ile ẹjọ, pẹlu awọn olori ogun, ati awọn enia nla ni ilu, Festu paṣẹ, nwọn si mu Paulu jade.