2 Nigbati a si wọ̀ ọkọ̀ Adramittiu kan, ti nfẹ lọ si awọn ilu ti o wà leti okun Asia, awa ṣikọ̀: Aristarku, ara Makedonia ti Tessalonika, wà pẹlu wa.
3 Ni ijọ keji awa de Sidoni. Juliu si ṣe inu rere si Paulu, o si bùn u láye ki o mã tọ̀ awọn ọrẹ́ rẹ̀ lọ lati ri itọju.
4 Nigbati awa si ṣikọ̀ nibẹ̀, awa lọ lẹba Kipru, nitoriti afẹfẹ ṣọwọ òdi.
5 Nigbati awa ré okun Kilikia on Pamfilia kọja, awa de Mira Likia.
6 Nibẹ̀ ni balogun ọrún si ri ọkọ̀ Aleksandria kan, ti nlọ si Itali; o si fi wa sinu rẹ̀.
7 Nigbati awa nlọ jẹ́jẹ li ọjọ pipọ, ti awa fi agbara kaka de ọkankan Knidu, ti afẹfẹ kò bùn wa làye, awa lọ lẹba Krete, li ọkankan Salmone;
8 Nigbati a si fi agbara kaka kọja rẹ̀, awa de ibi ti a npè ni Ebute Yiyanjú, ti o sunmọ ibiti ilu Lasea ti wà ri.