1 NIGBATI gbogbo wa si yọ tan ni awa mọ̀ pe, Melita li a npè erekuṣu na.
2 Kì si iṣe ore diẹ li awọn alaigbede na ṣe fun wa: nitoriti nwọn daná, nwọn si gbà gbogbo wa si ọdọ nitori òjo igba na, ati itori otutù.
3 Nigbati Paulu si ṣà ìdi iwọ́nwọ́n igi jọ, ti o si kó o sinu iná, pamọlẹ kan ti inu oru jade, o dì mọ́ ọ li ọwọ́.
4 Bi awọn alaigbede na si ti ri ẹranko oloró na ti dì mọ́ ọ li ọwọ́, nwọn ba ara wọn sọ pe, Dajudaju apania li ọkunrin yi, ẹniti o yọ ninu okun tan, ṣugbọn ti ẹsan kò si jẹ ki o wà lãye.
5 On si gbọ̀n ẹranko na sinu iná, ohunkohun kan kò ṣe e.