25 Nigbati ohùn wọn kò ṣọ̀kan lãrin ara wọn, nwọn tuká, lẹhin igbati Paulu sọ̀rọ kan pe, Otitọ li Ẹmí Mimọ́ sọ lati ẹnu woli Isaiah wá fun awọn baba wa,
26 Wipe, Tọ̀ awọn enia wọnyi lọ, ki o si wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati ni riri ẹnyin ó ri, ẹnyin kì yio si woye:
27 Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo lati fi gbọ́, oju wọn ni nwọn si ti dì: nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ati ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ati ki emi ki o má ba mu wọn larada.
28 Njẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, a rán igbala Ọlọrun si awọn Keferi, nwọn ó si gbọ́.
29 Nigbati o si ti sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn tan, awọn Ju lọ, nwọn ba ara wọn jiyàn pipọ.
30 Paulu si gbe ile àgbawọ rẹ̀ lọdun meji tọ̀tọ, o si ngbà gbogbo awọn ti o wọle tọ̀ ọ wá,
31 O nwasu ijọba Ọlọrun, o si nfi igboiya gbogbo kọ́ni li ohun wọnni ti iṣe ti Jesu Kristi Oluwa, ẹnikan kò da a lẹkun.