13 Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ.
14 Ṣugbọn ẹnyin sẹ́ Ẹni-Mimọ́ ati Olõtọ nì, ẹnyin si bere ki a fi apania fun nyin;
15 Ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ ìye, ẹniti Ọlọrun si ti ji dide kuro ninu okú; ẹlẹri eyiti awa nṣe.
16 Ati orukọ rẹ̀, nipa igbagbọ́ ninu orukọ rẹ̀, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ̀: ati igbagbọ́ nipa rẹ̀ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin.
17 Njẹ nisisiyi, ará, mo mọ̀ pe, nipa aimọ̀ li ẹnyin fi ṣe e, gẹgẹ bi awọn olori nyin pẹlu ti ṣe.
18 Ṣugbọn ohun ti Ọlọrun ti sọ tẹlẹ lati ẹnu gbogbo awọn woli wá pe, Kristi rẹ̀ yio jìya, on li o muṣẹ bẹ̃.
19 Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa ẹ̀ṣẹ nyin rẹ́, ki akoko itura ba le ti iwaju Oluwa wá,