24 Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn fi ọkàn kan gbé ohùn wọn soke si Ọlọrun nwọn si wipe, Oluwa, ìwọ ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn:
25 Iwọ nipa Ẹmi Mimọ́ ti o ti ẹnu Dafidi baba wa iranṣẹ rẹ wipe, Ẽṣe ti awọn keferi fi mbinu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan?
26 Awọn ọba aiye dide, ati awọn ijoye kó ara wọn jọ si Oluwa, ati si Kristi rẹ̀;
27 Nitõtọ sá ni, si Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ ti fi oróro yàn, ati Herodu, ati Pontiu Pilatu, pẹlu awọn keferi, ati awọn enia Israeli pejọ si,
28 Lati ṣe ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ati imọ rẹ ti pinnu ṣaju pe yio ṣẹ.
29 Njẹ nisisiyi, Oluwa, kiyesi ikilọ wọn: ki o si fifun awọn ọmọ-ọdọ rẹ lati mã fi igboiya gbogbo sọ ọ̀rọ rẹ.
30 Ki iwọ si fi ninà ọwọ́ rẹ ṣe dida ara, ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mã ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ.