30 Ki iwọ si fi ninà ọwọ́ rẹ ṣe dida ara, ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mã ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ.
31 Nigbati nwọn gbadura tan, ibi ti nwọn gbé pejọ si mi titi; gbogbo wọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si nfi igboiya sọ ọ̀rọ Ọlọrun.
32 Ijọ awọn ti o gbagbọ́ si wà li ọkàn kan ati inu kan: kò si si ẹnikan ti o pè ohun kan ninu ohun ini rẹ̀ ni ti ara rẹ̀: ṣugbọn gbogbo nwọn ni gbogbo nkan ṣọkan.
33 Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn.
34 Nitori kò si ẹnikan ninu wọn ti o ṣe alaini: nitori iye awọn ti o ni ilẹ tabi ile tà wọn, nwọn si mu owo ohun ti nwọn tà wá.
35 Nwọn si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli: nwọn si npín fun olukuluku, gẹgẹ bi o ti ṣe alaini si.
36 Ati Josefu, ti a ti ọwọ awọn aposteli sọ apele rẹ̀ ni Barnaba (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ọmọ-Itùnu), ẹ̀ya Lefi, ati ara Kipru.