22 A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe.
23 Nigbati o si di ẹni iwọn ogoji ọdún, o sọ si i lọkan lati lọ ibẹ̀ awọn ọmọ Israeli ará rẹ̀ wò.
24 Nigbati o si ri ọkan ninu wọn ti a njẹ ni ìya, o gbejà rẹ̀, o gbẹsan ẹniti nwọn njẹ ni ìya, o si lu ara Egipti na pa:
25 O si ṣebi awọn ará on mọ̀ bi Ọlọrun yio ti ti ọwọ́ on gbà wọn: ṣugbọn nwọn kò mọ̀.
26 O si di ijọ keji o yọ si wọn bi nwọn ti njà, on iba si pari rẹ̀ fun wọn, o wipe, Alàgba, ará li ẹnyin; ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ohun ti kò tọ́ si ara nyin?
27 Ṣugbọn ẹniti o finran si ẹnikeji rẹ̀ tì i kuro, o wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ wa?
28 Iwọ nfẹ pa mi gẹgẹ bi o ti pa ará Egipti laná?