28 Iwọ nfẹ pa mi gẹgẹ bi o ti pa ará Egipti laná?
29 Mose si sá nitori ọ̀rọ yi, o si wa ṣe atipo ni ilẹ Midiani, nibiti o gbé bí ọmọ meji.
30 Nigbati ogoji ọdún si pé, angẹli Oluwa farahàn a ni ijù, li òke Sinai, ninu ọwọ́ iná ni igbẹ́.
31 Nigbati Mose si ri i, ẹnu yà a si iran na: nigbati o si sunmọ ọ lati wò o fín, ohùn Oluwa kọ si i,
32 Wipe, Emi li Ọlọrun awọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Mose si warìri, kò si daṣa lati wò o mọ́.
33 Oluwa si wi fun u pe, Tú bata rẹ kuro li ẹsẹ rẹ: nitori ibi ti iwọ gbé duro nì ilẹ mimọ́ ni.
34 Ni riri mo ti ri ipọnju awọn enia mi ti mbẹ ni Egipti, mo si ti gbọ́ gbigbin wọn, mo si sọkalẹ wá lati gbà wọn. Wá nisisiyi, emi o si rán ọ lọ si Egipti.