39 Ẹniti awọn baba wa kò fẹ gbọ́ tirẹ, ṣugbọn nwọn tì i kuro lọdọ wọn, nwọn si yipada li ọkàn wọn si Egipti;
40 Nwọn wi fun Aaroni pe, Dà oriṣa fun wa ti yio ma tọ̀na ṣaju wa: nitori bi o ṣe ti Mose yi ti o mu wa ti ilẹ Egipti jade wá, a kò mọ̀ ohun ti o ṣe e.
41 Nwọn si yá ere ẹgbọ̀rọ malu ni ijọ wọnni, nwọn si rubọ si ere na, nwọn si nyọ̀ ninu iṣẹ ọwọ́ ara wọn.
42 Ọlọrun si pada, o fi wọn silẹ lati mã sìn ogun ọrun; bi a ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, Ẹnyin ara ile Israeli, ẹnyin ha mu ẹran ti a pa ati ẹbọ fun mi wá bi li ogoji ọdun ni iju?
43 Ẹnyin si tẹwọgbà agọ́ Moloku, ati irawọ oriṣa Remfani, aworan ti ẹnyin ṣe lati mã bọ wọn: emi ó si kó nyin lọ rekọja Babiloni.
44 Awọn baba wa ni agọ ẹri ni ijù, bi ẹniti o ba Mose sọrọ ti paṣẹ pe, ki o ṣe e gẹgẹ bi apẹrẹ ti o ti ri;
45 Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi;