52 Tani ninu awọn woli ti awọn baba nyin kò ṣe inunibini si? nwọn si ti pa awọn ti o ti nsọ asọtẹlẹ ti wíwa Ẹni Olõtọ nì; ẹniti ẹnyin si ti di olufihàn ati olupa:
53 Ẹnyin ti o gbà ofin, gẹgẹ bi ilana awọn angẹli, ti ẹ kò si pa a mọ́.
54 Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, àiya wọn gbọgbẹ́ de inu, nwọn si pahin si i keke.
55 Ṣugbọn on kún fun Ẹmí Mimọ́, o tẹjumọ́ ọrun, o si ri ogo Ọlọrun, ati Jesu nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.
56 O si wipe, Wò o, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ-enia nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.
57 Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara, nwọn si dì eti wọn, nwọn si fi ọkàn kan rọ́ lù u,
58 Nwọn si wọ́ ọ sẹhin ode ilu, nwọn sọ ọ lí okuta: awọn ẹlẹri si fi aṣọ wọn lelẹ li ẹsẹ ọmọkunrin kan ti a npè ni Saulu.