54 Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, àiya wọn gbọgbẹ́ de inu, nwọn si pahin si i keke.
55 Ṣugbọn on kún fun Ẹmí Mimọ́, o tẹjumọ́ ọrun, o si ri ogo Ọlọrun, ati Jesu nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.
56 O si wipe, Wò o, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ-enia nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.
57 Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara, nwọn si dì eti wọn, nwọn si fi ọkàn kan rọ́ lù u,
58 Nwọn si wọ́ ọ sẹhin ode ilu, nwọn sọ ọ lí okuta: awọn ẹlẹri si fi aṣọ wọn lelẹ li ẹsẹ ọmọkunrin kan ti a npè ni Saulu.
59 Nwọn sọ Stefanu li okuta, o si nképe Oluwa wipe, Jesu Oluwa, gbà ẹmí mi.
60 O si kunlẹ, o kigbe li ohùn rara pe, Oluwa, má kà ẹ̀ṣẹ yi si wọn li ọrùn. Nigbati o si wi eyi, o sùn.