13 Simoni tikararẹ̀ si gbagbọ́ pẹlu: nigbati a si baptisi rẹ̀, o si mba Filippi joko, o nwò iṣẹ àmi ati iṣẹ agbara ti nti ọwọ́ Filippi ṣe, ẹnu si yà a.
14 Nigbati awọn aposteli ti o wà ni Jerusalemu si gbọ́ pe awọn ara Samaria ti gbà ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn rán Peteru on Johanu si wọn:
15 Awọn ẹniti o si gbadura fun wọn, nigbati nwọn sọkalẹ, ki nwọn ki o le ri Ẹmí Mimọ́ gbà:
16 Nitori titi o fi di igbana kò ti ibà le ẹnikẹni ninu wọn; kìki a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa ni.
17 Nigbana ni nwọn gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si gbà Ẹmí Mimọ́.
18 Nigbati Simoni ri pe nipa gbigbe ọwọ́ leni li a nti ọwọ́ awọn aposteli fi Ẹmí Mimọ́ funni, o fi owo lọ̀ wọn.
19 O wipe, Ẹ fun emi na ni agbara yi pẹlu, ki ẹnikẹni ti mo ba gbe ọwọ́ le, ki o le gbà Ẹmí Mimọ́.