2 Awọn enia olufọkànsin si dì okú Stefanu, nwọn si pohùnrére ẹkún kikan sori rẹ̀.
3 Ṣugbọn Saulu, o ndà ijọ enia Ọlọrun ru, o nwọ̀ ojõjũle, o si nmu awọn ọkunrin ati obinrin, o si nfi wọn sinu tubu.
4 Awọn ti nwọn si túka lọ si ibi gbogbo, nwọn nwasu ọ̀rọ na.
5 Filippi si sọkalẹ lọ si ilu Samaria, o nwasu Kristi fun wọn.
6 Awọn ijọ enia si fi ọkàn kan fiyesi ohun ti Filippi nsọ, nigbati nwọn ngbọ́, ti nwọn si ri iṣẹ ami ti o nṣe.
7 Nitori ọpọ ninu awọn ti o ni ẹmi àimọ́ ti nkigbe lohùn rara, jade wá, ati ọpọ awọn ti ẹ̀gba mbajà, ati awọn amọ́kún, a si ṣe dida ara wọn.
8 Ayọ̀ pipọ si wà ni ilu na.