8 Ayọ̀ pipọ si wà ni ilu na.
9 Ṣugbọn ọkunrin kan wà, ti a npè ni Simoni, ti iti ima ṣe oṣó ni ilu na, ti isi mã jẹ ki ẹnu ya awọn ara Samaria, a mã wipe enia nla kan li on:
10 Ẹniti gbogbo wọn bọla fun, ati ewe ati àgba, nwipe, ọkunrin yi ni agbara Ọlọrun ti a npè ni Nla.
11 On ni nwọn si bọlá fun, nitori ọjọ pipẹ li o ti nṣe oṣó si wọn.
12 Ṣugbọn nigbati nwọn gbà Filippi gbọ́ ẹniti nwasu ihinrere ti ijọba Ọlọrun, ati orukọ Jesu Kristi, a baptisi wọn, ati ọkunrin ati obinrin.
13 Simoni tikararẹ̀ si gbagbọ́ pẹlu: nigbati a si baptisi rẹ̀, o si mba Filippi joko, o nwò iṣẹ àmi ati iṣẹ agbara ti nti ọwọ́ Filippi ṣe, ẹnu si yà a.
14 Nigbati awọn aposteli ti o wà ni Jerusalemu si gbọ́ pe awọn ara Samaria ti gbà ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn rán Peteru on Johanu si wọn: