16 Nitori emi o fi gbogbo ìya ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a.
17 Anania si lọ, o si wọ̀ ile na; nigbati o si fi ọwọ́ rẹ̀ le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́.
18 Lojukanna nkan si bọ kuro li oju rẹ̀ bi ipẹpẹ́: o si riran; o si dide, a si baptisi rẹ̀.
19 Nigbati o si jẹun, ara rẹ̀ mokun: Saulu si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin ni Damasku ni ijọ melokan.
20 Lojukanna o si nwasu Kristi ninu awọn sinagogu pe, Ọmọ Ọlọrun li on iṣe.
21 Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o ngbọ́, nwọn si wipe, Ẹniti o ti fõro awọn ti npè orukọ yi ni Jerusalemu kọ li eyi, ti o si ti itori na wá si ihinyi, lati mu wọn ni didè lọ sọdọ awọn olori alufa?
22 Ṣugbọn Saulu npọ̀ si i li agbara o si ndãmu awọn Ju ti o ngbe Damasku, o nfi hàn pe, eyi ni Kristi na.