37 O si ṣe ni ijọ wọnni, ti o ṣaisàn, o si kú: nigbati nwọn wẹ̀ ẹ tan, nwọn tẹ́ ẹ si yara kan loke.
38 Bi Lidda si ti sunmọ Joppa, nigbati awọn ọmọ-ẹhin gbọ́ pe Peteru wà nibẹ̀, awọn rán ọkunrin meji si i lọ ibẹ̀ ẹ pe, Máṣe jafara ati de ọdọ wa.
39 Peteru si dide, o si bá wọn lọ. Nigbati o de, nwọn mu u lọ si yara oke na: gbogbo awọn opó si duro tì i, nwọn nsọkun, nwọn si nfi ẹ̀wu ati aṣọ ti Dorka dá hàn a, nigbati o wà pẹlu wọn.
40 Ṣugbọn Peteru ti gbogbo wọn sode, o si kunlẹ, o si gbadura; o si yipada si okú, o ni, Tabita, dide. O si là oju rẹ̀: nigbati o si ri Peteru, o dide joko.
41 O si nà ọwọ́ rẹ̀ si i, o fà a dide; nigbati o si pè awọn enia mimọ́ ati awọn opó, o fi i le wọn lọwọ lãye.
42 O si di mimọ̀ yi gbogbo Joppa ká; ọpọlọpọ si gba Oluwa gbọ́.
43 O si ṣe, o gbé ọjọ pipọ ni Joppa lọdọ ọkunrin kan Simoni alawọ.