15 Nigbati ọkan ninu awọn ti o ba a joko tì onjẹ gbọ́ nkan wọnyi, o wi fun u pe, Ibukun ni fun ẹniti yio jẹun ni ijọba Ọlọrun.
16 Ṣugbọn o wi fun u pe, ọkunrin kan se àse-alẹ nla, o si pè enia pipọ:
17 O si rán ọmọ-odọ rẹ̀ ni wakati àse-alẹ lati sọ fun awọn ti a ti pè wipe, Ẹ wá; nitori ohun gbogbo ṣe tan.
18 Gbogbo wọn so bẹ̀rẹ, li ohùn kan lati ṣe awawi. Ekini wi fun u pe, Mo rà ilẹ kan, emi kò si le ṣe ki ng má lọ iwò o: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi.
19 Ekeji si wipe, Mo rà ajaga malu marun, mo si nlọ idán wọn wò: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi.
20 Ẹkẹta si wipe, Mo gbeyawo, nitorina li emi kò fi le wá.
21 Ọmọ-ọdọ na si pada de, o sọ nkan wọnyi fun oluwa rẹ̀. Nigbana ni bãle ile binu, o wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Jade lọ si igboro, ati si abuja ọ̀na, ki o si mu awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, ati awọn amukun, ati awọn afọju wá si ihinyi.