1 Nísinsin yìí, àwọn ará Fílístínì dojú ìjà kọ Ísírẹ́lì, Àwọn ará ísírélì sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí ọri òkè Gílíbóà
2 Àwọn ará Fílístínì sí lépa Sáúlù gidigidi àti àwọn ọmọ Rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ Rẹ̀. Jónátanì, Ábínádábù àti Málíkíṣúà.
3 Ìjà náà sì ń gbóná síi yí Sáúlù ká. Nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́.
4 Ṣọ́ọ̀lù sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é; Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà tirẹ̀ ó sì subú lé e.
5 Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Ṣọ́ọ̀lù ti kú, òhun pẹ̀lú subú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú.