13 Ó sì wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pásídámímù nígbà tí àwọn ará Fílístínì kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà báálì. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Fílístínì.
14 Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárin pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Fílístínì mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.
15 Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n (30) ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dáfídì wá lọ sí orí àpáta nínú ìhò Ádúlámù; Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Fílístínì sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Réfáímù.
16 Ní àsìkò náà Dáfídì sì wà nínú ibi gíga àti àwọn ará Fílístínì modi sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
17 Dáfídì sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Áà, ẹnìkan yóò ha buomi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù fún un mu?
18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Fílístínì, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ó sì gbé padà tọ Dáfídì wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa.
19 “Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe se èyí!” ó wí pé. “Se kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹnití ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dáfídì kò ní mu ú.Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.