13 Lẹ́ẹ̀kan síi àwọn ará Fílístínì gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì,
14 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì tún bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, Má se gòké tàrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká kí ẹ sì mú wọn níwájú igi Múlíbérì.
15 Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró yíyan ẹsẹ̀ ní orí òkè igi Bálísámù, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fi hàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Fílístínì.
16 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọ lu àwọn ọmọ ogun Fílístínì láti gbogbo ọ̀nà Gíbíónì lọ sí Géṣérì.
17 Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dáfídì tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, Olúwa sì mú kí gbogbo orílẹ̀ èdè bẹ̀rù Rẹ̀.