20 Ṣekaríyà, Ásíélì, Ṣémírámótì, Jẹ́híélì, Únínì, Élíábù, Máséíà àti Beniáyà àwọn tí ó gbọdọ̀ ta láétírì gẹ́gẹ́ bí àlámótì,
21 Àti Mátítíyà, Élíféléhù, Míkínéyà, Obedi-Édómù, Jélíélì àti Ásásíyà ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn goro, láti darí gẹ́gẹ́ bí Ṣémínítì.
22 Kénáníyá orin àwọn ará Léfì ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa Rẹ̀.
23 Bérékíà àti Ékáníyà ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.
24 Ṣébéáníá, Jóṣáfátì, Nétanélì, Ámásáyì, Ṣekaríyà, Beniáyà àti Élíásérì ní àwọn àlùfáà, ti o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Édómù àti Jéhíyà ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa láti ilé Obedi-Édómù, pẹ̀lú inú dídùn.
26 Nítori Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Léfì énì tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi sé ìrúbọ.