4 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ọmọ Léfì tí Dáfídì pèjọ papọ̀:
5 Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kóhátì;Úríélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.
6 Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Mórárì;Ásaíà olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.
7 Àádóje nínú àwọn ọmọ Gésóní;Jóẹ́lì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.
8 Igba nínú àwọn ọmọ Élísáfálì;Ṣémáíà olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.
9 Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hébírónì;Élíélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.
10 Méjìléláàdọ́fà nínú àwọn ọmọ Húsíélì;Ámínádábù olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.