2 Lẹ́yìn ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa.
3 Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Ísírẹ́lí ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èṣo àjàrà kan.
4 Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Léfì láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Ísírélì.
5 Ásáfù jẹ́ olóyè Ṣémírámótì, Jéhíelì, Mátítíyà, Élíábìlì, Bénáyà, Obedi-Édómù àti Jélíélì, Àwọn ni yóò lu lẹ́rì àti dùùrù háàpù. Ásáfù ni yóò lu símíbálì kíkan.
6 Àti Bénáià àti Jahaṣíélì àwọn àlùfáà ni yóò fọn ipè dédé níwájú àpótí ẹ̀rí méjẹ̀mú ti Ọlọ́run.
7 Ní ọjọ́ náà Dáfídì kọ́kọ́ fi lé Ásáfù àti àwon ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dáfídì ti ọpẹ́ sí Olúwa:
8 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ẹ pe orúkọ Rẹ̀,ẹ fi iṣẹ́ Rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe