1 Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin Rẹ̀, ó sọ fún Nátanì wòlíì pé, Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpèpè (igi) ààfin kédárì nígbà tí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wà lábẹ́ àgọ́
2 Nátanì dá Dáfídì lóhùn pé, Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.
3 Ní àsálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Nátanì wá, wí pé:
4 “Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé.
5 Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Isírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé.
6 Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Isírẹ́lì rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkankan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Ísírẹ́lì, tí èmí pàṣẹ́ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yín kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kédárì kọ́ fún mi?” ’