3 Ní àsálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Nátanì wá, wí pé:
4 “Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé.
5 Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Isírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé.
6 Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Isírẹ́lì rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkankan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Ísírẹ́lì, tí èmí pàṣẹ́ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yín kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kédárì kọ́ fún mi?” ’
7 “Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára wí: Èmi mú un yín láti pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.
8 Èmi ti wà pẹ̀lú yín ní, ibi kíbi tí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ̀mi sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀ta yín kúrò níwáju yín. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orukọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ̀ tí ó wà ní ayé.
9 Èmi yóò sì pèṣè àyè kan fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó lè ní ilé ti wọn kí a má sì se dàmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti se ní ìbẹ̀rẹ̀.