9 Èmi yóò sì pèṣè àyè kan fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó lè ní ilé ti wọn kí a má sì se dàmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti se ní ìbẹ̀rẹ̀.
10 Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì. Èmi pẹ̀lú yóò sẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀ta yín.“ ‘Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín:
11 Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀.
12 Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ títí láé.
13 Èmi yóò jẹ́ bàbá Rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kurò lọ́dọ̀ Rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo se mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú Rẹ̀.
14 Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ Rẹ̀ ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”
15 Nátanì ròyìn fún Dáfídì gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti Ìfihàn yí.