1 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.Réúbẹ́nì, Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Ṣébúlúnì,
2 Dánì, Jóṣẹ́fù, Bẹ́ńjámínì; Náfítanì, Gádì: àti Áṣérì.
3 Àwọn ọmọ Júdà:Érì, Ónánì àti Ṣélà, àwọn mẹ́tẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kénánì, ọmọbìnrin Súà Érì àkọ́bí Júdà, ó sì burú ní ojú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.
4 Támárì, aya ọmọbìnrin Júdà, ó sì bí Fárésì àti Ṣérà sì ní ọmọ márùn ún ní àpapọ̀
5 Àwọn ọmọ Fárésì:Hésírónì àti Hámúlù.
6 Àwọn ọmọ Ṣérà:Ṣímírì, Étanì, Hémánì, Kálíkólì àti Darà, gbogbo wọn jẹ́ márùn ún.
7 Àwọn ọmọ Kárímì:Ákárì, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Ísírẹ́lì nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.