32 Àwọn ọmọ Jádà, arákùnrin Ṣámáì:Jétérì àti Jónátanì. Jétérì sì kú láìní ọmọ.
33 Àwọn ọmọ Jónátanì:Pélétì àti Ṣásà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jéráhímẹ́lì.
34 Ṣésánì kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní.Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Éjíbítì tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Járíhà.
35 Ṣẹ́sánì sì fi ọmọ obìnrin Rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ Rẹ̀ Járíhà, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ Rẹ̀ jẹ́ Átaì.
36 Átaì sì jẹ́ baba fún Nátanì,Nátanì sì jẹ́ baba fún Ṣábádì,
37 Ṣábádì ni baba Éfúlálì,Éfúlálì jẹ́ baba Óbédì,
38 Óbédì sì ni baba Jéhù,Jéhù ni baba Ásáríyà,