6 Àwọn ọmọ Ṣérà:Ṣímírì, Étanì, Hémánì, Kálíkólì àti Darà, gbogbo wọn jẹ́ márùn ún.
7 Àwọn ọmọ Kárímì:Ákárì, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Ísírẹ́lì nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
8 Àwọn ọmọ Étanì:Áṣáríyà
9 Àwọn ọmọ tí a bí fún Hésírónì ni:Jéráhímélì, Rámù àti Kélẹ́bù.
10 Rámù sì ni babaÁmínádábù, àti Ámínádábù baba Náṣónì olórí àwọn ènìyàn Júdà.
11 Náṣónì sì ni baba Sálímà, Sálímà ni baba Bóásì,
12 Bóásì baba Óbédì àti Óbédì baba Jésè.