2 Dáfídì mú adé kúrò lórí àwọn ọba wọn ìwọ̀n Rẹ̀ dàbí i talẹ́ńtì wúrà, a sì tò ó jọ pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye. A sì gbé e ka orí Dáfídì. Ó kó ọ̀pọ̀ ìkógun láti ìlú ńlá náà.
3 Ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ jáde, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti ṣíṣẹ́ pẹ̀lú ayùn àti ìtulẹ̀ onírin àti àáké. Dáfídì ṣe eléyìí sí gbogbo àwọn ará ìlú Ámónì. Nígbà náà, Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun Rẹ̀ padà sí Jérúsálẹ́mù.
4 Ní ẹ̀yìn èyí ni ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Géṣérì pẹ̀lu àwọn ará Fílístínì, ní àkókò yìí ni Ṣíbékíà ará Húsà pa Ṣípáì, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Réfáì, àti àwọn ará Fílístínì ni a sẹ́gun.
5 Nínú ogun mìíràn pẹ̀lú àwọn ará Fílístínì, Élíhánánì ọmọ Jáírè pa Láhímì arákùnrin Gòláyátì ará àti, Gátì ẹni ti ó ní ọ̀kọ̀ kan tí ó dàbí ọ̀pá ahunsọ.
6 Síbẹ̀síbẹ̀ ninú ogun mìíràn, tí ó wáyé ní Gátì, ọkùnrin títóbi kan wà tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìka mẹ́fà ní ẹṣẹ̀ Rẹ̀ (24) Mẹ́rìnlélógún lápapọ̀. Òun pẹ̀lú wá láti Ráfà.
7 Nígbà tí ó fí Íṣírẹ́lì sẹ̀sín Jónátanì ọmọ Ṣíméà, àrákùnrin Dáfídì, sì pa á.
8 Wọ̀nyí ni ìran ọmọ Ráfà ní Gátì, wọ́n sì subú sí ọwọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin Rẹ̀.