15 Ọlọ́run sì rán ańgẹ́lì láti pa Jérúsálẹ́mù run. Ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì ti ń ṣe èyí, Olúwa sì ríi. Ó sì káàánú nítorí ibi báà, ó sì wí fún áńgẹ́lì tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Ańgẹ́lì Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.
16 Dáfídì sì wòkè ó sì rí áńgẹ́lì Olúwa dúró láàrin ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ Rẹ̀ tí ó sì nàá sórí Jérúsálẹ́mù. Nígbà náà Dáfídì àti àwọn àgbààgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.
17 Dáfídì sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo paláṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò dára, wọ̀nyí ni àgùntàn. Kí ni wọ́n ṣe? Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdíle mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-àrùn yìí kí ó dúró lóri àwọn ènìyàn rẹ.”
18 Nígbà náà ańgẹ́lì Olúwa náà pàṣẹ̀ fún Gádì láti sọ fún Dáfídì láti lọ sókè kí ó sì kọ́ pẹpẹ fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínánì ará Jébúsì.
19 Bẹ́ẹ̀ni Dáfídì sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gádì ti sọ ní orúkọ Olúwa.
20 Nígbà tí Órínánì sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí áńgẹ́lì; àwọn ọmọ Rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú Rẹ̀ pa ará wọn mọ́.
21 Nígbà náà Dáfídì sì súnmọ́, Nígbà tí Órínánì sì wò tí ó sì rí, ó sì kúrò ní ilẹ̀ ìpakà ó sì doju bolẹ̀ níwájú Dáfídì pẹ̀lú ojú Rẹ̀ ní ilẹ̀.