19 Bẹ́ẹ̀ni Dáfídì sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gádì ti sọ ní orúkọ Olúwa.
20 Nígbà tí Órínánì sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí áńgẹ́lì; àwọn ọmọ Rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú Rẹ̀ pa ará wọn mọ́.
21 Nígbà náà Dáfídì sì súnmọ́, Nígbà tí Órínánì sì wò tí ó sì rí, ó sì kúrò ní ilẹ̀ ìpakà ó sì doju bolẹ̀ níwájú Dáfídì pẹ̀lú ojú Rẹ̀ ní ilẹ̀.
22 Dáfídì sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè kọ́ pẹpẹ fún Olúwa, kí àjàkálẹ̀-àrùn lórí àwọn ènìyàn lè dúró. Tàá fún mi ní iye owó kíkún.”
23 Órínánì ni ó sọ fún Dáfídì pé, “Gbà á! Jẹ́ kí Olúwa ọba mi kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú Rẹ̀. Woó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ ọrẹ ṣiṣun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.”
24 Ṣùgbọ́n ọba Dáfídì dá Órínánì lóhùn pé, “Rárá, mo wà lórí àti san iye owó rẹ ní pípé, èmi kò sì ní mú fún Olúwa èyí tí ó jẹ́ tìrẹ, tàbí láti rú ẹbọ ọrẹ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.”
25 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì san ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà fún Órínánì nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà.