1 Kíróníkà 22:8-14 BMY

8 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi.

9 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún-un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀ta Rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ Rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Sólómónì, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ fún Ísírẹ́lì lásìkò ìjọba Rẹ̀.

10 Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba Rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdi ìtẹ́ ìjọba Rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì láéláé.’

11 “Nísinsìn yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.

12 Kí Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ se aláṣẹ lórí Ísírẹ́lì, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́.

13 Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mósè fun Ísírẹ́lì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́.

14 “Èmi ti gba Ìpọ́nju ńlá láti ṣe fún ile Olúwa ọ̀kẹ́ márùn ún talẹ́ńtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà, Ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn.