18 Àwọn ọmọ Ísárì:Ṣélómítì sì ni ẹni àkọ́kọ́.
19 Àwọn ọmọ Hérónì:Jéríyà sì ni ẹni àkọ́kọ́, Ámáríyà sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jáhásíélì sì ni ẹ̀ẹ̀kẹta àti Jékáméámù ẹ̀ẹ̀kẹrin.
20 Àwọn ọmọ Húsíélì:Míkà ni àkọ́kọ́ àti Íṣíà ẹ̀ẹ̀kejì.
21 Àwọn ọmọ Mérárì:Máhílì àti Músì.Àwọn ọmọ Máhílì:Élíásárì àti Kísì.
22 Élíásérì sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kísì, sì fẹ́ wọn.
23 Àwọn ọmọ Músì:Málì, Édérì àti Jérímótì mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Léfì bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa