1 Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Árónì:Àwọn ọmọ Árónì ni Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì.
2 Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; Bẹ́ẹ̀ ni Élíásérì àti Ítamárì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
3 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ṣádókì ọmọ Élíásérì àti Áhímélékì ọmọ Ítamárì, Dáfídì sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.
4 A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Élíásérì ju lára àwọn ọmọ Ítamárì lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rindínlógún (16) olórí láti ìdílé ọmọ Élíásérì ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Ítamárì.
5 Wọ́n sì pín wọn lótìítọ́ nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olorí ilé Ọlọ́run wà láàrin àwọn ọmọ méjèèjì Élíásérì àti Ìtamárì.