4 A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Élíásérì ju lára àwọn ọmọ Ítamárì lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rindínlógún (16) olórí láti ìdílé ọmọ Élíásérì ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Ítamárì.
5 Wọ́n sì pín wọn lótìítọ́ nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olorí ilé Ọlọ́run wà láàrin àwọn ọmọ méjèèjì Élíásérì àti Ìtamárì.
6 Ṣémáíà ọmọ Nétanélì, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Ṣádókù Àlùfáà, Áhímélékì ọmọ Ábíátarì àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Éléásári àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Ítamárì.
7 Ìpín èkíní jáde sí Jéhóíáríbù,èkejì sí Jédáià,
8 Ẹlẹ́kẹta sì ni Hárímù,ẹ̀kẹ́rin sì ní Ṣéórímù,
9 Ẹ̀karùn-ún sì ni Maíkíyà,ẹlẹkẹ́fà sì ni Míjámínì,
10 Ẹ̀kẹ́je sì ni Hakósì,ẹlẹ́kẹ́jọ sí ni Ábíjà,