1 Pẹ̀lúpẹ̀lú Dáfídì àti àwọn olórí àwọn ọmọ ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì fún ìsìn àsọtẹ́lè, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin àti kínbálì. Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí:
2 Nínú àwọn ọmọ Ásáfù:Ṣákúrì, Jóṣẹ́fù Nétanáíà àti Ásárélà, àwọn ọmọ Ásáfù ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Ásáfù, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba.
3 Gẹ́gẹ́ bí ti Jédútúnì, nínú àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀:Gédálià, Ṣérì, Jéṣáíà, Ṣíméhì Háṣábíà àti Mátítíyà, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jédútúnì, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti lati yin Olúwa:
4 Gẹ́gẹ́ bí ti Hémánì, nínú àwọn ọmọ Rẹ̀:Búkíà, Mátaníyà, Usíélì, Ṣúbáélì àti Jérímótì; Hánáníyà, Hánánì, Élíátà, Gídáítì àti Rámámútì Ésérì; Jósíbékáṣà, Málótì, Hótírì àti Máhásíótì.