16 Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣálélà-etí ẹnu ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣúpímì àti Hósà.Olùsọ́ wà ní ẹ̀bá Olùsọ́:
17 Àwọn ará Léfì mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúṣù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra.
18 Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnrarẹ̀.
19 Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ ti kórà àti Mérà.
20 Àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Léfì wọn wà ní ìdí ilé ìfowópamọ́ sí ti ile Ọlọ́run àti ilé ohun èlò yíyà sọ́tọ̀.
21 Àwọn ìran ọmọ Ládánì tí wọn jẹ́ ará Géríṣónì nípaṣẹ̀ Ládánì àti tí wọn jẹ́ àwọn olorí àwọn ìdílé tí ó jẹ́ ti Ládánì ará Gérísónì ni Jehíélì,
22 Àwọn ọmọ Jehíélì, Ṣétámì àti arákùnrin Rẹ̀ Jóélì. Wọ́n ṣalábojútó ilé ìṣúra ti ilé ìṣúra ti ilé Olúwa.