24 Ṣúbáélì, ìran ọmọ Gérísómì ọmọ Mósè jẹ́ oníṣẹ́ tí ó bojútó ilé ìṣúra
25 Àwọn ìbátan Rẹ̀ nípaṣẹ̀ Élíeṣérì: Réhábíà ọmọ Rẹ̀, Jéṣáíà ọmọ Rẹ̀, Jórámì ọmọ Rẹ̀.
26 Ṣélómítì àti àwọn ìbátan Rẹ̀ jẹ́ alábojútó ilé ìṣúra fún àwọn ohun tí à ti yà sọ́tò nípa ọba Dáfídì, nípaṣẹ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ alákóso ọrọrún àti nipaṣẹ̀ alákóṣo ọmọ-ogun mìíràn.
27 Díẹ̀ nínú ìkógun tí wọ́n kó nínú ogun ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún títún ilé Olúwa ṣe.
28 Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì aríranl àti nípasẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, Ábínérì ọmọ Nerì àti Joábù ọmọ Ṣeruíà gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣélómítì àti àwọn ìbátan Rẹ̀.
29 Láti ọ̀dọ̀ àwọn Iṣíhárì: Kénáníà àti àwọn ọmọ Rẹ̀ ni a pín iṣẹ́ ìsìn fún kúrò ní apá ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn onísẹ́ àti àwọn adájọ́ lórí Ísirẹ́lì.
30 Láti ọ̀dọ̀ àwọn Hébírónì: Háṣábíà àti àwọn ìbátan Rẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀san (17,000) ọkùnrin alágbára ní ó dúró ni Ísírẹ́lì, ìhà ìwọ̀ oòrùn Jórólánì fún gbogbo iṣẹ́ Olúwa àti fún iṣẹ́ ọba.