1 Kíróníkà 26:28-32 BMY

28 Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì aríranl àti nípasẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, Ábínérì ọmọ Nerì àti Joábù ọmọ Ṣeruíà gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣélómítì àti àwọn ìbátan Rẹ̀.

29 Láti ọ̀dọ̀ àwọn Iṣíhárì: Kénáníà àti àwọn ọmọ Rẹ̀ ni a pín iṣẹ́ ìsìn fún kúrò ní apá ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn onísẹ́ àti àwọn adájọ́ lórí Ísirẹ́lì.

30 Láti ọ̀dọ̀ àwọn Hébírónì: Háṣábíà àti àwọn ìbátan Rẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀san (17,000) ọkùnrin alágbára ní ó dúró ni Ísírẹ́lì, ìhà ìwọ̀ oòrùn Jórólánì fún gbogbo iṣẹ́ Olúwa àti fún iṣẹ́ ọba.

31 Níti àwọn ará Hébírónì, Jéríyà jẹ́ olóyè wọn gẹ́gẹ́ bí ìwé ìrántí ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní ti ìdílé wọn. Ní ọdún kẹrin ìjọba Dáfídì, a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí, àwọn ọkùnrin alágbára láàrin àwọn ará Hébíronì ni a rí ní Jáṣérì ní Gílíádì.

32 Jéríyà ní ẹgbàáméjì, àti ọgọ́rin méje ìbátan, tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbára àti olórí àwọn ìdilé ọba Dáfídì sì fi wọ́n ṣe àkóso lórí àwọn ará Reúbẹ́nì àwọn ará Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè fun gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jọ mọ́ ti Ọlọ́run àti fún ọ̀ràn ti ọba.