11 Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Ṣíbékáì ará Húṣátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
12 Ẹ̀kẹsàn-án fún oṣù kẹ́sàn-án jẹ́. Ábíésérì ará Ánátótì, ará Bénjámínì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
13 Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹ́wàá jẹ́ Máháráì ará Nétófátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
14 Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Bénáyà ará pírátónì ará Éfíráímù ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
15 Ìkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Hélídáì ará Nétófátì láti ìdílé Ótíníélì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
16 Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Ísírẹ́lì:lórí àwọn ará Réúbẹ́nì: Éliésérì ọmọ Ṣíkírì;lórí àwọn ará Ṣíméónì: Ṣéfátíyà ọmọ Mákà;
17 lórí Léfì: Háṣábíà ọmọ Kémúélì;lori Árónì: Ṣádókù;