1 Àwọn ọmọ Júdà:Fárésì, Hésírónì, Kárímì, Húrì àti Ṣóbálì.
2 Réáíà ọmọ Ṣóbálì ni baba Jáhátì, àti Jáhátì baba Áhúmáyì àti Láhádì. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Ṣórà.
3 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Étanílù:Jésírélì, Ísímà, Ídíbásì, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Sélélípónì
4 Pénúélì sì ni baba Gédórì, àti Édérì baba Húṣà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Húrì, Àkọ́bí Éfúrátà àti baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
5 Áṣárì bàbá Jékóà sì ní aya méjì, Hélà àti Nárà.