22 Tókímù, ọkùnrin kósébà, àti Jóáṣì àti sáráfù, olórí ní Móábù àti Jáṣúbì Léhémù. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́).
23 Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Nítaímù àti Gédérà; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń sisẹ́ fún ọba.
24 Àwọn Ọmọ Síméónì:Némúélì, Jámínì, Járíbì, Ṣérà àti Ṣáúlì;
25 Ṣálúmù sì jẹ́ ọmọ Ṣáúlì, Míbísámù ọmọ Rẹ̀ Miṣima ọmọ Rẹ̀.
26 Àwọn ọmọ Míṣímà:Hámúélì ọmọ Rẹ̀ Sákúrì ọmọ Rẹ̀ àti Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀.
27 Síméì sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìndínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Júdà.
28 Wọ́n sì ń gbé ní Béríṣébà, Móládà, Hásárì Ṣúálì,