27 Síméì sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìndínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Júdà.
28 Wọ́n sì ń gbé ní Béríṣébà, Móládà, Hásárì Ṣúálì,
29 Bílà, Ésémù, Tóládì,
30 Bétúélì, Hórímà, Síkílágì,
31 Bẹti máríkóbótì Hórímà; Hásárì Ṣúsímù, Bẹti Bírì àti Ṣáráímì. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dáfídì,
32 agbégbé ìlú wọn ni Étamù Háínì, Rímónì, Tókénì, Áṣánì àwọn ìlú márùnún
33 Àti gbogbo ìletò tí ó wà ní agbégbé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti dé Bálì Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn, wọ́n sì pa ìwé ìtàn ìdílé mọ́.