8 Àti Bélà ọmọ Ásásì ọmọ Ṣémà, ọmọ Jóẹ́lì tí ń gbé Áróérì àní títí dé Nébò àti Baaliméónì.
9 Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àti wọ ihà láti odo Yúfúrátè; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ si i ní ilẹ̀ Gílíádì.
10 Àti ní ọjọ́ Ṣọ́ọ̀lù, wọ́n bá àwọn ọmọ Hágárì jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gílíádì.
11 Àti àwọn ọmọ Gádì ń gbé ọ̀kánkán wọn, ní ilẹ̀ Básánì títí dé Sálíkà:
12 Jóẹ́lì olórí, Ṣáfámù ìran ọmọ, Jánáì, àti Ṣáfátì ni Básánì,
13 Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní:Míkáélì, Mésúlímù Ṣébà, Jóráì, Jákánì, Ṣíà àti Hébérì méje.
14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ábíháílì, ọmọ Húrì, ọmọ Járóà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Míkàẹ́lì, ọmọ Jésíháì, ọmọ Jádò ọmọ Búsì.