32 Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin ńiwájú Àgọ́ ìpàdé títí tí Ṣólómónì fi kọ́ ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n se iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.
33 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn:Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kóhátítè:Hémánì olùkọrin,ọmọ Jóẹ́lì, ọmọ Ṣámúẹ́lì,
34 Ọmọ Élíkánáhì ọmọ Jéróhámù,ọmọ Élíéli, ọmọ Tóhà
35 Ọmọ Ṣúfì, ọmọ Élíkáná,ọmọ Máhátì, ọmọ Ámásáyì,
36 Ọmọ Élíkánà, ọmọ Jóẹ́lì,ọmọ Ásárááhì, ọmọ Ṣéfáníáhì
37 Ọmọ Táhátì, ọmọ Áṣírì,ọmọ Ébíásáfì ọmọ Kóráhì,
38 ọmọ Íṣíhárì, ọmọ Kóhátìọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì;